IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 7 August 2025

Nitori agbado meji to ji, Oloye Ajibade si fun Ebenezer ni majele mu n'Ileṣa


Ọkunrin oloye kan niluu Ileṣa, Gbenga Ajibade, lo ti wa lakolo awọn ọlọpaa bayii lori ẹsun pe o fun ọmọkunrin kan to ji agbado meji ninu oko rẹ ni majele mu.


Ninu fidio kan to n lọ kaakiri bayii, agbegbe Ireti Ayọ niluu Ileṣa niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lopin ọsẹ to kọja.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi ̣ṣalaye pe ṣe ni Oloye Ajibade, ẹni ọdun mejilelọgọta ka Ebenezer, ẹni ọdun marundinlọgbọn mọ inu oko rẹ nibi to ti ji agbado meji ya.


O ni lẹyin ti baba yii lu Ebenezer tan lo tun fun un ni nnkan kan to jẹ majele mu, ṣugbọn nigba ti ọmọ yii pada de ile wọn lawọn araadugbo sare gbe e lọ si ọsibitu, ti awọn dokita si tete ba agbara majele naa jẹ lara rẹ.


Ọjẹlabi sọ siwaju pe bi iroyin ṣe de ọdọ baba to bi Ebenezer pe wọn ti fun ọmọ rẹ ni majele mu nibi to ti lọọ jale ni aya baba naa ja sodi, o si gbabẹ ku.


O sọ siwaju pe ọwọ ti tẹ Ajibade bayii, o si ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ l'Oṣogbo ninu iwadi wọn.

No comments:

Post a Comment