IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 2 September 2025

2026: Benedict Alabi bẹrẹ ifikunlukun kaakiri ipinlẹ Ọṣun, o ṣeleri iṣejọba alakoyawọ


Lori erongba rẹ lati du tikẹẹti ẹgbẹ APC nimurasilẹ fun idibo gomina, igbakeji gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi, ti bẹrẹ ifikunlukun kaakiri ọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress.


N ẹkun idibo Iwo ati Ẹdẹ, tilutifọn lawọn ọmọ ẹgbẹ APC fi ki i kaabọ, wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii oloṣelu to ni gbongbo ni ẹsẹkuuku, ti ki i si foju tẹmbẹlu ẹnikẹni.




Ni Iwo, to fi mọ ijọba ibilẹ Ayedire, Ọlaoluwa, gbogbo wọn ni wọn ṣeleri lati ṣugba Alabi, wọn ni erongba rẹ yoo tubọ mu iṣọkan wa ninu ẹgbẹ APC.


Bakan ni awọn eeyan ẹkun idibo Ẹdẹ, labẹ eyi ti ijọba ibilẹ Ariwa Ẹdẹ, Guusu Ẹdẹ, Ejigbo ati Ẹgbẹdọrẹ, wa, gba Alabi tọwọtẹṣe, wọn sọ ọ ni  'Ta a n wa, Ta a ri'.



Nigba to n ba wọn sọrọ lọna mejeeji, Benedict Alabi dupẹ lọwọ awọn agbaagba ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC patapata fun iduroṣinṣin wọn ati ipinnu ọkan lati pada sile ijọba.


O ni afojusun oun ni lati ṣeto ijọba alakoyawọ ati lati ri i pe ogo to ti sọnu mọ ipinlẹ Ọṣun lọwọ latigba ti ẹgbẹ onitẹsiwaju ti kuro nijọba pada.

No comments:

Post a Comment