IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 13 September 2025

A ti kẹkọọ lara ohun to ṣẹlẹ lasiko idibo ọdun 2022 l'Ọṣun, ko le ṣẹlẹ mọ - BOA


Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun ana, Benedict Olugboyega Alabi, ti sọ pe ki i ṣe pe ẹgbẹ All Progressives Congress kuna ninu idibo gomina to waye lọdun 2022 nipinlẹ naa, magomago ibo ati wahala ti awọn ẹgbẹ Peoples Democratic Party da silẹ lo fa a ti nnkan fi ri bo ṣe ri.


Alabi, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si BOA, lo ti fi erongba rẹ han lati dije funpo gomina Ọṣun lọdun 2026 bayii, ti erongba rẹ si ti jẹ itẹwọgba kaakiri ọdọ awọn agbaagba ẹgbẹ APC.


Nigba to n sọrọ lori ohun to fa ijakulẹ ẹgbẹ naa lọdun 2022, Alabi ṣalaye pe ẹgbẹ APC jẹ ẹgbẹ to bọwọ fun ofin idibo, to si bọwọ fun awọn oludibo, bẹẹ ni awọn ko gbagbọ ninu idibo onijagidijagan.


O ni ṣugbọn awọn ko mọ pe tikutiye ni awọn ẹgbẹ PDP fẹẹ fi idibo igba naa ṣe, iyẹn lo si fa a ti omi fi tẹyin bọgbin lẹnu. Amọ ṣa, o ni awọn yoo tubọ mura lorii eto aabo lasiko idibo lọdun 2026, ki ohun to ṣẹlẹ lọdun 2022 ma baa tun waye mọ.


Alabi ṣalaye pe bi awọn janduku ṣe n gbe apoti ibo kaakiri nigba naa, ni wọn n dunkoko mọ ẹmi awọn oludibo, bẹẹ ni eru ibo wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, gbogbo eleyii si lawọn yoo dena rẹ lọdun to n bọ nitori awọn araalu ti gbọn si i, wọn si ti mọ iyatọ laarin ẹgbẹ mejeeji.


O fi kun ọrọ rẹ pe iyapa diẹ to tun wa ninu ẹgbẹ APC ṣaaju idibo ọdun 2022 wa lara nnkan to ṣakoba fun wọn, amọ ni bayii, gbogbo ọmọ ẹgbẹ ti wa niṣọkan pẹlu afojusun gbigba ijọba Ọṣun pada lọdun 2026.


BOA ṣalaye pe eto iṣejọba ti yoo mu igbayegbadun awọn araalu lọkunkundun lo wa lọkan oun ti oun fi pinnu lati dupo gomina, oniruuru iṣẹ idagbasoke ti awọn eeyan mọ ẹgbẹ onitẹsiwaju mọ loun yoo si ṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun lai fi si ibikan ju ibikan lọ ti oun ba lanfaani lati de ipo naa.

No comments:

Post a Comment