IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 13 September 2025

Lẹyin ọsẹ meji, Adeleke sọrọ lori ọrọ Apetumodu ti wọn ju sẹwọn l'Amẹrika


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti paṣẹ fun kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Doṣu Babatunde, lati gbe igbesẹ kiakia lori ọrọ Apetumodu, Ọba Joseph Oloyede, ti wọn ju sẹwọn lorileede Amẹrika.


Inu oṣu kẹjọ ọdun yii ni ile ẹjọ kan lorileede Amẹrika ju Apetunodu si ẹwọn ọdun mẹrin aabọ lori ẹsun pe o fi owo iranwọ Covid-19 lu jibiti.


Nigba ti awọn oniroyin beere igbesẹ tijọba Ọṣun fẹẹ gbe lori ọrọ yii ni Babatunde sọ pe awọn yoo gba ojulowo idajọ naa, CTC, ki awọn to le gbe igbesẹ kankan.


Ọrọ yii ti di eyi ti awọn ọlọmọọba ilu naa sọ pe awọn ko nigbagbọ ninu awọn afọbajẹ mọ, ti wọn si ni ẹlẹwọn ko le pada de waa jọba le awọn lori.


Ninu ipade awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ to waye lalẹ ọjọ Furaidee to kọja ni Gomina Adeleke ti waa paṣẹ fun kọmiṣanna yii lati gbe igbesẹ lori ọrọ naa lai fi falẹ mọ.


Bakan naa ni awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ fọwọ si orukọ Ọmọọba Adeleke Saheed Adeyẹmi gẹgẹ bii Olokusa ti ilu Okusa nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ.

No comments:

Post a Comment