Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lati ẹkun idibo Iwọ-Oorun Ọṣun ti ke si awọn adari ẹgbẹ naa lati ro ti iduroṣinṣin ati bi wọn ṣe mu ọrọ ẹgbẹ lọkunkundun lati le mu oludije funpo gomina lati ọdọ wọn.
Ajọ eleto idibo orileede yii ti kede ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026 gẹgẹ bii ọjọ idibo gomina ipinlẹ Ọṣun.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade oloṣooṣu ti wọn ṣe nijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun yii, eleyii ti alaga wọn, Hon. Ọmọlaoye Akintọla fọwọ si, ni wọn ti sọ pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC latọdọ wọn ni wọn n ṣe deede ninu ẹgbẹ.
Wọn dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC Ọṣun ti wọn ti n ba wọn lọọgun erongba wọn yii, eleyii ti wọn ni ohun to bojumu, ti yoo si duro gẹgẹ bii pinpin nnkan dọgbandọgba ninu ẹgbẹ naa ni.
Ninu ipade naa ni wọn ti ṣeleri atilẹyin fun awọn adari ẹgbẹ naa, bẹrẹ lati ipinlẹ titi de wọọdu.
Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun bo ṣe ri i daju pe ijọba ibilẹ ni ominira nipa eto iṣuna.
Wọn tun dupẹ lọwọ Minisita fun ọrọ okoowo ati igbokegbodo ọkọ lori omi, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetọla fun bo ṣe n ran ẹgbẹ naa lọwọ loorekoore, ti ko si kuna ninu ojuṣe rẹ gẹgẹ bii aṣaaju ẹgbẹ l'Ọṣun.
No comments:
Post a Comment