IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 28 September 2025

Ipinlẹ Ọṣun yatọ si Ẹdo, ṣe lawọn araalu maa run yin pa l'Ọṣun - PDP Ọṣun kilọ fun APC


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ọṣun ti kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress lati maṣe gbero pe awọn yoo lo jagidijagan lati gba ipinlẹ Ọṣun lasiko idibo gomina to n bọ.


Alaga ẹgbẹ naa, Hon. Sunday Bisi ṣalaye ninu atẹjade kan pe irọ patapata ni ariwo ti ẹgbẹ oṣelu APC n pa kaakiri bayii pe awọn fẹẹ da wahala silẹ l'Ọṣun.


Bisi sọ pe aitete m'ole lọrọ ẹgbẹ APC, ko sẹni ti ko mọ pe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe ni wọn maa n parọ pe ẹloniran fẹẹ ṣe, ṣugbọn ọkọ baalu to ti gbera ni wọn n ṣẹwọ si l'Ọṣun.


O ni oniruuru aṣeyọri Gomina Ademọla Adeleke ti jẹ ki awọn araalu nifẹẹ rẹ, ko si ṣee ṣe fun ẹgbẹ APC lati fi ija gba ipinlẹ Ọṣun bi wọn ṣe ṣe nipinlẹ Edo nitori arunpa lawọn araalu yoo run ẹgbẹ wọn loṣu kẹjọ ọdun 2026.


O ni dipo ariwo lasan ti wọn n pa, ibeere to ṣe pataki ti awọn araalu n beere lọwọ wọn bayii ni ki wọn wa idahun si, lai jẹ bẹẹ, o tumọ si pe ẹgbẹ APC ti fi ipilẹ nnkan buburu lelẹ lorileede Naijiria nipasẹ owo kansu ti wọn gba lọna aitọ.


Bisi sọ pe ṣe ni ki ẹgbẹ oṣelu APC Ọṣun jade sita, ki wọn sọ inu akanti ti wọn gba owo kansu si, iye ti wọn gba ati awọn oṣiṣẹ kansu ti wọn buwọ lu owo naa.

No comments:

Post a Comment