Ọkan lara awọn oloṣelu nijọba ibilẹ Ayedire nipinlẹ Ọṣun, Ọlawuni Rotimi, ti sọ pe laarin awọn oludije to ti fi erongba wọn lati dupo gomina han bayii, Benedict Olugboyega Alabi nikan loun ni igboya pe o ni ọrọ awọn ọdọ lọkan.
Ọlawuni, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Eleniyan, sọ pe oun atawọn akẹgbẹẹ oun joko, awọn si yannayanna oniruuru ileri ti awọn oludije n ṣe, awọn ri i pe ti Alabi ba lanfaani lati gba tikẹẹti ẹgbẹ APC, yoo jẹ itẹwọgba fun gbogbo awọn oludibo nipinlẹ Ọṣun.
Lasiko ti Eleniyan atawọn eeyan rẹ ko oniruuru awọn nnkan ipolongo ibo lọ si ọfiisi BOA niluu Oṣogbo lati fi ṣatilẹyin fun un lo ṣalaye pe oniruuru iṣẹ ti n lọ labẹlẹ lati ri i pe BOA ati ẹgbẹ oṣelu APC jawe olubori ninu idibo ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ilanilọyẹ ti n lọ kaakiri lati jẹ ki awọn araalu jade lati forukọ silẹ fun kaadi idibo alalopẹ to n lọ lọwọ, ki wọn le lanfaani lati dibo.
O fi kun ọrọ rẹ pe ẹni to ba mọ Alabi daadaa lasiko to jẹ igbakeji fun Alhaji Gboyega Oyetọla yoo mọ pe ẹni takuntakun to mọ nipa eto iṣakoso ati eto oṣelu ni ọkunrin naa.
Ọlawuni sọ pe olootọ eniyan, to si ni ifẹ awọn araalu lọkan ni Alabi, yoo si mu iyipada nla ba ipinlẹ Ọṣun ti ẹgbẹ oṣelu APC ba le fa a kalẹ.
O waa ke si awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC lati fa BOA kalẹ nitori iriri to ni ninu oṣelu, bẹẹ lo ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati jumọ ṣiṣẹ fun un nitori ajọṣe tolori-tẹlẹmu ni aṣeyọri erongba rẹ.
No comments:
Post a Comment