IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 10 September 2025

Lobatan! Awọn afọbajẹ ilu Ipetumodu sọ pe awọn ko le rọ ọba to n ṣẹwọn loye o


Wahala nla lo bẹ silẹ niluu Ipetumodu nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ nipinlẹ Ọṣun lọjọ Tusidee ọsẹ yii nigba ti olori awọn afọbajẹ sọ pe oun ko le rọ ọba wọn, Joseph Oloyede, loye.


Apetumodu, Ọba Oloyede, nile ẹjọ giga kan lorileede Amẹrika ju si ẹwọn ọdun mẹrin loṣu to kọja lori ẹsun fifi owo iranwọ Corvid 19 lu jibiti.


Nibi ipade kan ti gbogbo awọn ọlọmọọba ilu naa ṣe laafin Apetumodu nirọlẹ ọjọ Tusidee ni awọn kan ti sọ pe ki awọn afọbajẹ kọwe si Gomina Ademọla Adeleke pe ko si ọba mọ niluu naa, ki wọn si yan eeyan meji lati rọpo awọn afọbajẹ meji ti wọn ti ku.


Ṣugbọn afọbajẹ to dagba ju niluu naa lọwọlọwọ, Aṣalu, Oloye Sunday Adedeji, yari kanlẹ, o ni ko si nnkan to jọ bẹẹ. 


O ni kaka ki oun gbe iru igbesẹ bẹẹ, oun yoo fi ipo silẹ gẹgẹ bii afọbajẹ ni.


A gbọ pe ọrọ naa da wahala nla silẹ, loju ẹsẹ si ni ipade tuka.

2 comments:

  1. I have every evidence ogunsua of modakeke sent modakeke youth leader Mr Lawrence aka Olowo Obinrin and his boys to my resident in modakeke to kill me

    ReplyDelete