IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 16 September 2025

Nipinlẹ Ondo, Bọsẹde pa ẹgbọn rẹ nitori ẹgbẹrin naira


Bọsẹde Iluyẹmi lo ti wa lakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo bayii lori ẹsun pe o ba ẹgbọn rẹ ja, to si yọri si iku.


Ẹgbẹrin naira ti ẹgbọn rẹ, Ọmọwumi Tẹwọgboye, jẹ ẹ la gbọ pe o da ija silẹ.


Ṣe ni Bọsẹde beere owo tomaati ati ata ti Ọmọwumi ra lọwọ rẹ lawin, nigba ti iyẹn si n tẹwọ pẹbẹpẹbẹ ni ọrọ naa di ariwo.


Ṣe ni Bọsẹde lọ aṣọ mọ ẹgbọn rẹ lọrun, ti iyẹn ṣubu lulẹ looro, to si farapa yannayanna.


Wọn sare gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn o ti gbẹmi mi ki wọn too debẹ.


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo fidi ọrọ naa mulẹ. Agbẹnusọ wọn, DSP Oluṣọla Ayanlade, ṣalaye pe Bọsẹde ti wa lakolo awọn, bẹẹ ni yoo foju bale ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment