Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti gbe ọpa aṣẹ fun Oloke Olooru ti Oke-Olooru nijọba ibilẹ Boluwaduro, Ọba Adebisi Mukaila Micheal Oyegbadebọ.
Nibi eto naa to waye ninuu sẹkiteriati ijọba niluu Oṣogbo ni Gomina Ademọla Adeleke, ẹni ti kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ, Amofin Doṣu Babatunde, ṣoju fun, ti ke si ọba naa lati la ri i daju pe alaafia tubọ n jọba niluu rẹ.
Babatunde sọ pe ki ọba yii ri igbega rẹ si ọba onipo keji gẹgẹ bii ipe si iṣẹ idagbasoke agbegbe rẹ.
Ọba Oyegbadebọ lati ile ọlọmọọba Ogboolu niluu Oke-Olooru Ikinifin, lo jẹ Olokeolooru kẹrindinlọgbọn, ṣugbọn oun ni ọba akọkọ ti yoo gba ọpa aṣẹ latọdọ ijọba niluu naa.
Wolii ati oludasilẹ ijọ Christ Awareness ni Ọba Adebisi, bẹẹ lo tun jẹ oludasilẹ Hamin Mukaila Adebisi King's Polytechnic Limited.
Nigba to n dupẹ, Ọba Adebisi gboṣuba fun Gomina Adeleke fun bo ṣe mu ọrọ idagbasoke awọn ẹsẹkuku lọkunkundun.
O ṣeleri pe eto aabo yoo tubọ munadoko sii lasiko rẹ, bẹẹ ni alaafia, iṣọkan ati itẹsiwaju ko nii gbẹyin nibẹ.
Bakan naa lo rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati gba kaadi idibo alalopẹ, ki wọn si ṣatilẹyin fun saa keji Gomina Ademọla Adeleke ni gbogbo ọna.
No comments:
Post a Comment