Gomina Ademọla Adeleke ti sọ pe bi oniruuru awọn oludaṣẹsilẹ ṣe n wọ ipinlẹ Ọṣun wa bayii ṣafihan pe awọn eeyan kaakiri agbaye nigbẹkẹle kikun ninu iṣejọba to wa lode.
Nigba to n ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ redio aladani tuntun kan, Bass 99.3 FM, eleyii to wa lagbegbe Olude niluu Oṣogbo, ni Adeleke sọ pe ọkan lara afojusun ijọba oun ni lati jẹ ki okoowo ati iṣẹ ṣiṣe rọrun fun gbogbo olugbe ipinlẹ Ọṣun.
O ni idasilẹ Bass 99. 3 FM jẹ igbesẹ igboya, o si fi igbagbọ ti oludasilẹ rẹ, Ẹkundayọ Salawu, ni ninu ipinlẹ Ọṣun han.
Adeleke, ẹni ti igbakeji rẹ, Ọmọọba Kọla Adewusi, Abẹnugan ile igbimọ aṣofin, Adewale Ẹgbẹdun, kọmiṣanna fun eto iroyin, Kọlapọ Alimi, ba kọwọrin lọ sibẹ, sọ siwaju pe ileeṣẹ redio naa yoo tubọ fun awọn araalu lanfaani si iroyin igbadegba lẹkajẹka.
Yatọ si eleyii, Gomina Adeleke sọ pe idasilẹ redio naa yoo tun din ainiṣe lọwọ lawujọ ku nitori awọn ọdọ yoo lanfaani si iṣẹ nibẹ, nipasẹ eyi ti idagbasoke yoo ba eto ọrọ aje ipinlẹ Ọṣun.
Ṣaaju ninu ọrọ oludasilẹ redio naa, Ẹkundayọ, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si DJ Bassman, o dupẹ lọwọ Gomina Adeleke fun atilẹyin rẹ lori imuṣẹ iran naa, o si ṣeleri pe redio ọhun yoo wa fun idaraya ati idagbasoke ọmọniyan.
No comments:
Post a Comment