Ile mejeeji to n jọba niluu Ipetumodu nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ nipinlẹ Ọṣun, iyẹn ile Aribile ati Fagbemokun, ti kọ lẹta si Gomina Ademọla Adeleke lati kede pe ipo Apetumodu wa lofo.
Bakan naa ni wọn ni kijọba rọ Ọba Joseph Oloyede loye latari bo ṣe n ṣẹwọn lọwọ lorileede Amẹrika lori ẹsun jibiti lilu.
Oṣu Kẹjọ ọdun yii ni adajọ kan nile ẹjọ giga lorileede Amẹrika ju Apetumodu, Ọba Oloyede, sẹwọn oṣu mẹrindinlọgọta lori ẹsun fifi owo iranwọ Corvid 19 lu jibiti.
Ninu lẹta kan ti awọn aṣoju marun-marun ninu idile mejeeji fọwọ si lọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa ọdun yii ni wọn ti sọ pe iwa ti Ọba Oloyede hu ti ko abuku ba awọn ọmọ ilu naa kaakiri agbaye.
Wọn ni o ti ba orukọ ilu Ipetumodu jẹ, o si ti doju ti awọn, nitori naa ki gomina lo agbara rẹ labẹ ofin ibilẹ lati kede rirọ ọba naa loye.
Wọn fi kun ọrọ wọn pe ọpọlọpọ aṣa ati iṣe ilu naa ni ina rẹ ti jo ajorẹyin lati ọdun méta ti ọba yii ko ti si laafin, idi si niyẹn tijọba fi gbọdọ gbe igbesẹ kiakia lorii rẹ.

No comments:
Post a Comment