Ọkan lara awọn ti wọn wa ninu sẹẹli ni olu-ileeṣẹ Amọtẹkun to wa ni Powerline niluu Oṣogbo, Mayọwa Awẹ, ti sọ pe lẹyin ti awọn Amọtẹkun yinbọn mọ oun lẹsẹ loun tun ti lo odidi ọsẹ marun ninu sẹẹli wọn.
Lasiko ti awọn ọlọpaa ẹka IRT niluu Abuja lọ si ọfiisi awọn Amọtẹkun lati lọ wo awọn ti wọn ti mọle ni Mayọwa, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Bisọọbu, ṣalaye lọjọ Tọsidee to kọja pe igbo ni awọn Amọtẹkun ka mọ aburo oun lọwọ lagbegbe Idasa niluu Ileṣa.
O sọ siwaju pe lẹyin ti wọn mu aburo oun pẹlu igbo ti owo rẹ to ẹgbẹrun marunlelogun naira ni wọn beere ẹgbẹrun lọna irinwo naira gẹgẹ bii owo beeli.
Mayọwa sọ siwaju pe bi aburo oun ṣe pe oun latọdọ awọn Amọtẹkun loun sọ fun un pe seeni kan wa ninu baagi oun ti oun le lọọ ta, oun si ṣeleri lati ko owo rẹ lọ sọdọ wọn.
O ni oun ko mọ pe wọn ti duro de oun sibi ileepo kan nitosi ọfiisi wọn, bi oun si ṣe debẹ ni wọn yinbọn mọ oun lẹsẹ lati ori ọkada ti oun wa, ti wọn si gbe oun pẹlu ẹjẹ lọ sinu sẹẹli wọn, ki wọn to ko awọn mejeeji lọ siluu Oṣogbo.
Amọ sa, olori ẹka IRT lati Abuja, SP Rotimi Ogunmuyiwa ati igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa Ọṣun ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ, Bayọnle Sulaiman, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ si agọ ọlọpaa to ba wa nitosi wọn kikakia fun ẹkunrẹrẹ iwadii lori ẹsun yoowu ti wọn ba fi kan wọn.

No comments:
Post a Comment