Alaga igbimọ ajọ to n ri si eto ilera adojutofo ọfẹ tijọba ipinlẹ Ọṣun n ṣe, Osun Health Insurance Agency, Dokita Muyiwa Ọladimeji, ti sọ pe bi awọn ọmọ orileede yii ṣe maa n sa lọ si Oke-okun lati gba itọju ko le dawọ duro ayafi tijọba lẹkajẹka ba bẹrẹ sii nawo to tọ lori eto ilera.
O ni aisi awọn irinṣẹ igbalode to kunju osunwọn pẹlu awọn dokita to to kaakiri awọn ileewosan wa lara awọn nnkan to n ṣokunfa lilọ kaakiri ọhun.
Nigba to n dahun ibeere nibi eto kan ti agbarijọpọ awọn oniroyin to ti fẹyinti nipinlẹ Ọṣun, League of Veteran Journalists, ṣagbekalẹ rẹ ni Ọladimeji ti sọ pe ko si ẹni ti yoo fẹ lati padanu awọn eeyan rẹ lai tii pe ọjọ, niwọn igba ti wọn ba si ti lagbara lati lọ fun iwosan loke-okun, kia ni wọn yoo lọ.
O ni awọn irinṣẹ tijọba ipinlẹ ko ba le ra si awọn ọsibitu ijọba, o yẹ ki ijọba apapọ le ra wọn, o ni eleyii ni yoo jẹ ki awọn araalu tubọ ni igbẹkẹle kikun ninu awọn ọsibitu orileede wa.
Ni ti awọn oloṣẹlu ti wọn maa n ṣagbere ẹgbẹ kaakiri, Ọladimeji ṣalaye pe aini oye kikun nipa oṣelu ati ibẹru ijakulẹ lo maa n fa a. O ni ẹni to ba mọ pe araalu loun fẹẹ sin yoo mọ pe oun gbọdọ duro ninu ẹgbẹ oṣelu ti oun ba wa, nigba to ba dun, ati nigba ti ko dun.
Ọladimeji sọ siwaju pe aini ati oṣi to tun ti gbilẹ lorileede yii tun maa n mu ki awọn oloṣelu bẹ kaakiri nigba to jẹ pe wọn ti ni i lọkan pe lai si ninu ẹgbẹ oṣelu to wa nijọba, awọn ko le rọwọ mu.
Lori ahesọ to n lọ kaakiri pe Gomina Ademọla Adeleke fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party bọ sinu ẹgbẹ All Progressives Congress, Ọladimeji ṣalaye pe irọ to jinna soootọ ni ọrọ naa.
O ni loootọ lawọn aṣaaju ẹgbẹ naa l'Ọṣun ṣabẹwo sọdọ Aarẹ Bọla Tinubu lati ṣeleri atilẹyin wọn fun un lori ibo apapọ ọdun 2027, idi ti awọn si fi ṣe bẹẹ ni pe ko si ẹnikẹni to sọrọ pe Buhari ko gbọdọ lo saa meji lasiko tirẹ, nitori naa, ẹnikẹni ko gbọdọ di Tinubu lọwọ lati lo saa meji ti iran Yoruba naa.
O ni digbi ni Adeleke wa ninu ẹgbẹ PDP, gbogbo awọn araalu ti wọn fẹran itẹsiwaju iṣẹ ribiribi to n ṣe l'Ọṣun bayii ni wọn si n sọ pe ko duro ninu ẹgbẹ PDP, saa keji si daju fun un.
Ni ti ajọ OHIA, Ọladimeji ṣalaye pe awọn to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun ni wọn ti n janfaani eto naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii, gbogbo awọn ọsibitu to si wa labẹ eto naa lawọn maa n tọpinpin wọn lati ri i pe wọn ko yẹsẹ ninu ilana ajọ naa.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, alaga awọn oniroyin to ti fẹyinti ọhun, Adetoyeṣe Shittu Alamu, ṣapejuwe Dokita Muyiwa Ọladimeji gẹgẹ bii oloṣelu to ni ọrukọ rere, to si ṣe e ṣawokọṣe fun awọn ọjẹwẹwẹ oloṣelu.

No comments:
Post a Comment