Lamẹẹtọ kan nipa ọrọ to n lọ lawujọ, Oluwatosin Babatunde, ti ke si gbogbo awọn ti itẹsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Ọṣun jẹ logun lati maṣe faaye gba ohun ti ko ba tọna ninu ipo adari awọn alaga ẹgbẹ oṣelu, iyẹn Intra-Party Advisory Council, IPAC.
Babatunde ṣalaye pe ajọ naa gbọdọ jẹ eyi to da duro, ti ko si ni nnkan kan ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu to ba n ṣejọba lọwọ, eleyii to ni yoo fun wọn lanfaani lati ṣe ojuṣe wọn bo ti yẹ.
O ni iroyin kan to n lọ kaakiri bayii pe ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Accord, Pasitọ Victor Akande, ni erongba lati du ipo alaga IPAC jẹ eyi to ṣajeji patapata.
O ni bawo ni alaga ẹgbẹ ti gomina ipinlẹ Ọṣun wa yoo ṣe tun jẹ alaga IPAC? Ninu alaye rẹ, ẹni ti yoo jẹ alaga IPAC gbọdọ jẹ eeyan to le duro gbena wojuu ijọba to ba wa lode to ba di pe wọn n ṣe nnkan to tako igbayegbadun awọn araalu.
Babatunde ni ko ṣee ṣe fun alaga ẹgbẹ oṣelu kan lati sọrọ ta ko gomina ẹgbẹ rẹ, eyi to si ti yatọ si ilana ominira ti IPAC ni latigba ti wọn ti da a silẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, "IPAC gbọdọ jẹ ajọ olominira, eyi to da duro, ko le ṣee ṣe fun ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba, ko tun jẹ alaga IPAC"

No comments:
Post a Comment