Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Lere Oyewumi, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ACCORD bayii.
Oyewumi, ẹni to jẹ igbakeji olori awọn aṣofin to kere ju, lo gba kaadi ẹgbẹ Accord ni Ward 9, nijọba ibilẹ Irewọle lọjọ Aje, Mọnnde ọsẹ yii.
Ni bayii, ipinlẹ Ọṣun ni Sẹnetọ kan atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ mẹfa ninu ẹgbẹ oṣelu Accoed, nigba ti awopn Sẹnetọ meji atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ mẹta wa ninu ẹgbẹ APC.

No comments:
Post a Comment