IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 22 October 2024

Ki n le rowo tọju iyawo mi ni mo ṣe ji ọkada - Rasheed


Ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Rasheed Abdullahi, ni ọwọ ajọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii fun ẹsun ole jija. 


Gẹgẹ bi alakoso ajọ naa, Dokita Ọmọyẹle Isaac Adekunle, ṣe ṣalaye, ilu Omu Aran nipinlẹ Kwara ni Rasheed ti ji ọkada naa, o si gbe e wa siluu Ila Ọrangun nipinlẹ Ọṣun lati maa fi ṣiṣẹ. 


Ọmọyẹle ṣalaye pe lasiko ti ọkunrin naa n gbe ọkada Bajaj ti ko ni nọmba ọhun kaakiri lawọn amọtẹkun da a duro, ti ko si le ṣalaye ibi to ti ri i fun wọn. 


Lẹyin ti wọn tẹ ẹ ninu daadaa lo jẹwọ pe ṣe loun ji ọkada naa ati pe bi oun ṣe ji i loun ti ko ẹru oun kuro niluu Omu-Aran. 


Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Rasheed sọ pe ara iyawo oun ti ko ya loun fẹẹ fi owo ọkada naa tọju, idi si niyẹn ti oun fi ji i. 


O ni ṣe loun ṣọ ẹni to ni ọkada naa lasiko tiyẹn fẹẹ lọ kirun ninuu mọṣalaaṣi, ati pe bo ṣe wọbẹ loun ji ọkada naa gbe, ti oun si mori le ilu Ila-Ọrangun. 


Ọmọyẹle waa fi da awọn araalu loju pe ipinlẹ Ọṣun ko nii gba awọn ọbayejẹ, o ni ẹni to ni ọkada naa ti yọju, bẹẹ lawọn yoo taari Rasheed sọdọ awọn amọtẹkun ipinlẹ Kwara lati tẹ siwaju ninu iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment