Gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, ti sọ pe to ba jẹ pe baba oun wa laye ni, oun ko ba ti lanfaani lati lọ sidi iṣẹ sọja laelae.
Oyinlọla, ẹni to jẹ oludasilẹ Alọlade Oyinlọla College of Health Sciences and Information Technology niluu Okuku ṣalaye pe baba oun korira iṣẹ ṣọja nigba aye rẹ.
O ni ohun ti baba oun to jẹ Olokuku ti ilu Okuku nigba naa maa n tẹnumọ ni pe Ọmọọba ki i ṣe iṣẹ ṣọja, awọn ti ki i ṣe ọmọọba ni wọn le maa gbọ orukọ wọn nidi iṣẹ sọja.
Nibi ayẹyẹ ilanilọyẹ ti wọn ṣe fun awọn iṣi-kinni akẹkọọ kọlẹẹji naa to waye ninu ọgba ileewe ọhun ni Oyinlọla ti sọ pe ogún kan ṣoṣo ti baba oun fun gbogbo awọn ọmọ mẹrindinlaadọrin to bi ni ẹkọ to ye kooro.
O ni niwọn igba ti ko si si ẹni ti ko rin nilana ẹkọ laarin awọn, ko si ẹni to ranti pe baba awọn fi ogun kan silẹ depoo pe wọn yoo pin ogun rẹ lati ọdun mẹrinlelọgọta to ti jade laye.
Oyinlọla rọ awọn akẹkọọ naa lati mọ pe ogun kan ṣoṣo ti awọn obi ati alagbatọ wọn le fi le wọn lọwọ ni ẹkọ, o ni anfaani nla ni yoo jẹ fun wọn ti wọn ba le foju si ẹkọ wọn ni kọlẹẹji naa.
O ni, gẹgẹ bii iṣi-kinni awọn akẹkọọ, ojuṣe wọn ni lati fi ipilẹ rere lelẹ fun awọn akẹkọọ ti yoo tun maa wa si ileewe naa, ki wọn si tẹriba labẹ ibawi.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọjọgbọn Peter Okebukọla, ṣalaye pe akẹkọọ bii ọgọfa ni wọn gba fọọmu kọlẹẹji ọhun, awọn mẹtadinlaadọrin ni wọn si ti wa fun iforukọsilẹ.
O ni kọlẹẹji naa yoo fi iyun lelẹ nipa eto ilera lorileede Naijiria nitori awọn olukọ ti wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ ni wọn yoo maa kọ awọn akẹkọọ naa.
Okebukọla fi da awọn akẹkọọ naa, pẹlu awọn obi wọn ti wọn wa nibẹ loju pe, laipẹ ni kọlẹẹji naa yoo di apewaawo kaakiri agbaye nitori awọn ọmọ ọlọpọlọ pipe ninu imọ ilera ni wọn yoo maa jade latibẹ.
No comments:
Post a Comment