IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 31 October 2024

Loootọ mi o ba Gomina Adeleke ṣe papọ mọ, ṣugbọn yoo wọle idibo ọdun 2026 - Jumokol


Aṣaaju kan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party l'Ọṣun, Sẹnetọ Felix Ogunwale, ti sọ pe awọn oniruuru iṣẹ idagbasoke to n ṣẹlẹ l'Ọṣun ti fi han pe yoo rọrun fun Gomina Ademọla Adeleke lati wọle saa keji lọdun 2026.


Nigba to n kopa lori eto ori redio kan ni Ogunwale, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Jumokol, ti ṣalaye pe loootọ oun ko ṣe papọ pẹlu Adeleke mọ, ṣugbọn oun ni idaniloju pe didun lọsan 2026 yoo so fun un.


Gẹgẹ bo ṣe wi, ''Ọmọkunrin yẹn n gbiyanju, beeyan ba wo biriiji ti wọn n ṣe lọna Alekuwodo lọ si Government House, afi ẹni ti ko ba ṣiṣẹ owo ri. 


''Adeleke maa wọle ibo ọdun 2026, bi mi o ba a ṣe pọ mọ, mi o le ba a ja debii wi pe ko ma wọle. Mi o ba a ṣe pọ mọ, mọ si sọ fun un, mi o ṣe e ni kọrọ. 


''Mọ sọ fun un pe 'Oloye, Gomina, Sẹnetọ Nurudeen Ademọla Adeleke, mi o si pẹlu rẹ mọ, ṣugbọn mi o fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ'. 


''Ṣe ẹ mọ pe tawọn eeyan ba gbadun irọ-pipa, ko si bi wọn a ṣe fẹran olootọ, emi o mọ bi wọn ṣe maa n la'tan ninu oṣelu. 


''Idi ti mi o fi ba gomina ṣe mọ ni pe mo lọọ fi ọrọ lọ ọ, wọn o tiẹ beere wo, ṣugbọn lẹyin ti mo sọrọ yii o, awọn eeyan ti wa, gomina naa si ti sọ pe awọn n bọ, tori naa, mi o nii fẹẹ sọrọ lori rẹ mọ''


Lori eto ọrọ-aje orileede Naijiria, Sẹnetọ Ogunwale sọ pe oun o le gbadura pe ki Tinubu ṣubu, o ni bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu awọn yatọ, ẹni ti ẹgbẹ PDP ba gbe silẹ loun yoo duro ti, ṣibẹ oun ko le gbadura pe ki ohunkohun ṣelẹ si i.

No comments:

Post a Comment