Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Comfort Ọlajumọkẹ Ọlalere Tinubu, lo ti gun ọkọ rẹ, Oluṣẹgun Tinubu pa lagbegbe Adegbayi niluu Ibadan nipinlẹ Ọyọ.
Tinubu, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lo pade iku ojiji lọwọ iyawo rẹ lọgbọnjọ oṣu kẹwaa ọdun yii ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ.
Ọdun mẹta sẹyin la gbọ pe awọn tọkọtaya yii ṣegbeyawo, ọmọ meji si ti wa laarin wọn.
Gbagede gbọ pe lalẹ ọjọ naa, Oluṣegun Tinubu fẹsun kan iyawo rẹ pe o tilẹkun yaara wọn lati aago meje aarọ to ti jade titi to fi pada wọle laago meje alẹ.
Ọrọ yii la gbọ o da wahala silẹ to fi di igbaju-igbamu laarin awọn mejeeji. Gẹgẹ bi ọkan lara awọn mọlẹbi wọn to gbe pẹlu wọn ṣe sọ, lẹyin to ba wọn pari ija yẹn niyawo pada sinuu yaara, ti ọkọ si sun palọ.
Ṣugbọn ibinu yii ko tan ninuu Ọlajumọkẹ, bo ṣe ri i pe ọkọ rẹ sun tan lo mu ọbẹ, o si fi gun un lẹyin. Ariwo ti ọkunrin yii pa lo ji awọn araale to ku, wọn si gbe e digbadigba lọ si ọsibitu.
Lẹyin ọgbọn iṣeju la gbọ pe Tinubu jade laye. Awọn ọlọpaa Gbagi ni wọn kọkọ mu iyawo ọhun, ko too di pe wọn taari ọrọ rẹ si SCID ni Iyaganku.
No comments:
Post a Comment