IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 5 November 2024

Awakọ bọọsi binu tan, o dana sun ara rẹ ati oṣiṣẹ LASTMA to fẹẹ mu un


Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ileewosan ti oṣiṣẹ ajọ Lagos State Transport Management Authority, LASTMA, kan ti n gba itọju lo wa lẹyin ti awakọ bọọsi kan rọ epo bẹntiroolu le e lori, to si sọna si i. 


Kayeefi ni ọrọ naa jẹ fun awọn eeyan agbegbe Mile 2 niluu Eko laarọ ọjọ Tusidee, ọjọ karun oṣu kọkanla ọdun yii. 


A gbọ pe ṣe ni dẹrẹba ọkọ bọọsi T4 to ni nọmba LSD 355 Ck ọhun wa iwakuwa, eleyii to tako ofin irinna nipinlẹ Eko, idi si niyẹn ti awọn oṣiṣẹ LASTMA ṣe fẹẹ mu un. 


Nigba ti ariyanjiyan naa le laarin dẹrẹba ọkọ naa, kọndọkitọ rẹ, atawọn oṣiṣẹ LASTMA, inu bi i, o gbe kẹẹgi bẹntiroolu to wa ninu ọkọ rẹ, o si fọn ọn si oṣiṣẹ naa lara, bẹẹ ni o fọn si ara oun naa paapaa. 


Bo ṣe ju ina sara oṣiṣẹ LASTMA ni ina dahun lara tiẹ naa, ti ọrọ si di bo o lọ, o ya lọna nibẹ. 


Manija ajọ LASTMA, Ọlalekan Badmus-Oki, ṣalaye pe oṣiṣẹ naa ti n gba itọju nileewosan nitori o farapa pupọ, o si kilọ pe ajọ naa ko nii faaye gba awakọ kankan lati tapa si ofin irinna nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment