IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 5 November 2024

Arẹgbẹṣọla For Senator: Ẹ ma da wọn lohun o, awọn alabosi ati abanilorukọjẹ ni wọn wa nidi ẹ - Ọmọluabi Progresives


Igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Ọṣun, Ọmọluabi Progressives, ti sọ pe iṣẹ ọwọ awọn alabosi ni posita kan ti wọn n gbe kaakiri bayii ninu eyi ti wọn ti sọ pe Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla fẹẹ dije dupo aṣofin ti yoo ṣoju awọn eeyan Ila-Oorun ipinlẹ Ọṣun lọdun 2027.


Laipe yii ni ahesọ naa n lọ kaakiri pe labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni Arẹgbẹṣọla, gomina tẹlẹ l'Ọṣun ati Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii nigba kan ri, ti fẹẹ dupo naa. 


Ṣugbọn akọwe ipolongo fun Ọmọluabi Progressives, Oluwaseun Abọsẹde, ti sọ pe irọ to jinna soootọ ni ahesọ naa. 


O ni ko sẹni to le gba kannbo lọwọ imu, ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Arẹgbẹṣọla, ko si figba kankan sọ ri pe oun darapọ mọ ẹgbẹ PDP ka to waa sọ pe yoo dupo kankan nibẹ. 


Abọsẹde sọ siwaju pe awọn ti jinnijinni mu nipa bi Omọluabi Progressives ṣe n ran bii oorun kaakiri kọrọkọndu ipinlẹ Ọṣun bayii ni wọn wa nidii posita naa. 


O ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati de fila ma-wo-bẹ si ahesọ naa, ki wọn si mọ pe digbi ni Arẹgbẹṣọla wa ninu ẹgbẹ APC. 


O sọ siwaju pe ṣe lawọn agbesunmọmi naa n wa gbogbo ọna lati ja Arẹgbẹṣọla lulẹ, wọn si ti gbagbe pe ẹni ti Ọlọrun ba sure fun, ko si ẹni to le fi re.

No comments:

Post a Comment