IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 28 May 2025

Tirela to n ko ẹran Ileya lọ siluu Ikire lati Kebbi ko sodo, eeyan meji lo ku


O kere tan, eeyan meji lo gbẹmi mi, nigba ti ọpọlọpọ farapa nibi ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ lagbegbe Oke-Ọfa niluu Gbọngan nipinlẹ Ọṣun.


Gbagedeọrọ gbọ pe lati Kebbi ni tirela to ko ẹran Ileya ọhun ti n bọ, ilu Ikire lo si n lọ kiṣẹlẹ naa to ṣẹlẹ lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii.


Gẹgẹ bi awọn to wa lagbegbe ibẹ ṣe sọ, o ṣee ṣe ko jẹ pe ṣe ni dẹrẹba ọkọ naa sun lọ lasiko ti wọn de ibi ti omi ẹrọfọ naa wa, to si yiwọ sọna inu omi.


A gbọ pe eeyan mejidinlogun to fi mọ dẹrẹba ni wọn wa pẹlu awọn maalu naa ninu tirela ọhun, loju ẹsẹ si leeyan meji gbẹmi mi.


Awọn ẹṣọ alaabo bii Amọtẹkun, ọlọpaa, sifu difẹnsi wa lara awọn ti wọn doola awọn to wa nibẹ, ti wọn si gbe wọn lọ sileewosan fun itọju.

No comments:

Post a Comment