IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 27 May 2025

Ileeṣẹ iwakusa Sẹgilọla ṣ'aṣepọ pẹlu ajọ ologun oju ofurufu ilẹ wa lori eto ilera


Lara ojuṣe rẹ lori igbayegbadun awọn eeyan agbegbe ti wọn ti n ṣiṣẹ, ileeṣẹ iwakusa Sẹgilọla Resources and Operations Limited (SROL) ti ko oogun oyinbo (medical supplies) ti owo rẹ to miliọnu meji naira fun ileeṣẹ ọmọ ologun oju ofurufu ilẹ wa.


Eleyii wa lara ọna lati kin ileeṣẹ awọn ologun oju ofurufu lọwọ fun ami ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta ti wọn n ṣe ninu eyi ti wọn ti ya ọjọ kan sọtọ fun ipese ilera ọfẹ.



Gẹgẹ bi alakoso ẹka ilera fun SROL, Dokita Prince Osuchukwu, ṣe ṣalaye, ọkan lara afojusun ileeṣẹ naa ni bi idagbasoke yoo ṣe maa ba orileede Naijiria ati bi aye yoo ṣe rọrun fun awọn araalu.


O ni o pọn dandan fawọn lati kin ileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ wa lọwọ lati ṣami ayẹyẹ irinajo nla yii, ni pataki julọ, lati le pese ilera to peye fawọn eeyan agbegbe ti awọn ti n ṣiṣẹ.



Yatọ si awọn nnkan ilera yii, o ni ileeṣẹ Sẹgilọla Resources and Operations Limited tun fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira lati mu ki eto naa kẹsẹjari.


Ninu ọrọ tirẹ, kọmandanti fun Nigerian Air Force (NAF) Institute of Safety, Ipetu-Ijeṣha, Group Captain Abdulkadir Bello, gboṣuba fun ileeṣẹ SROL, o ni awọn ni ileeṣẹ ti awọn kọkọ kan si nipa eto naa, wọn si jẹ awọn ni waransesa.



O ni ko tii si ileeṣẹ to fun awọn ni nnkan to to eyi ti awọn ri gba ni SROL, o si ṣeleri ibaṣepọ to dan mọran laarin ileeṣẹ ologun ati SROL.

No comments:

Post a Comment