Ajọ kan to maa n topinpin bi eto idibo yoo ṣe ri, Geopolitics Survey International (GSI) ti gbe abọ iwadi abala akọkọ nipa idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026 jade bayii.
Gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ to n dari ajọ naa, Dokita Adeyẹmọ Adeyẹfa ṣe ṣalaye, eeyan ẹgbẹrun marun lati ẹkun idibo kọọkan kaakiri ẹkun idibo mẹsẹẹsan to wa nipinlẹ Ọṣun ni wọn kopa ninu iwadi naa.
O ni abala mẹta lawọn pin ibeere si lori idibo to n bọ ọhun, lara rẹ ni pe ẹgbẹ oṣelu wo lawọn olukopa ninu iwadi naa yoo dibo fun, oludije wo ni wọn yoo dibo fun ati pe ki ni idi ti wọn fi yan iru oludije bẹẹ laayo.
Ninu esi awọn olukopa ti wọn ko jọ laarin oṣu kẹrin si oṣu karun ọdun yii ni wọn ti sọ pe ida mẹẹdogun ninu ọgọrun mu ẹgbẹ APC, ida marundinlaadọrin ninu ọgọrun gba lati dibo fun PDP, nigba ti ida mẹwaa to ku gba lati dibo fun awọn ẹgbẹ oṣelu to ṣẹku.
Labala keji, ida mẹrindinlaadọrin ninu ọgọrun faramọ Gomina Adeleke, ida marun faramọ Ajibọla Basiru, ida mẹfa faramọ Ọtunba Iyiọla Omiṣore, ida mẹjọ faramọ Bọla Oyebamiji, ida marun faramọ Najeem Salam, ida mẹrin faramọ Moshood Adeoti, nigba ti awọn ida mẹfa to ku ko tii mọ oludije ti wọn yoo dibo fun.
Adeyẹfa ṣalaye pe awọn ṣakojọpọ esi iwadii naa pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ kan ni Fasiti Ileṣa ki aṣiṣe ma baa si ninuu rẹ, oniruuru awọn iṣẹ idagbasoke to si n lọ lọwọ l'Ọṣun bayii ni pupọ awọn to mu Adeleke sọ pe o fa a ti awọn fi mu un.
O ni abala mẹrin lawọn pin iwadii naa si, abajade abala akọkọ niyii, laipẹ ni abala mẹta to ku yoo jade lẹsẹẹsẹ.
No comments:
Post a Comment