IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 June 2025

L'Ọṣun, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija siraa wọn nibi ọdun eegun, ni wọn ba yinbọn pa Kazeem


Eni ori yọ o dile lọrọ ri lagbegbe Oke-Ọla niluu Oṣogbo lalẹ ọjọ Sannde ọjọ kin-in-ni oṣu kẹfa ọdun yii nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija siraa wọn, ti wọn si pa ọkunrin kan ti wọn pe ni Kazeem.


Gbagede gbọ pe ori ni wọn ti yinbọn fun ọmọkunrin naa, loju ẹsẹ lo si ku.


Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣojuu rẹ ṣe wi, eegun kan ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn pe ni Ẹiyẹ Confraternity tẹle lọ si agbegbe Oke-Ọla, bi wọn ṣe debẹ ni wọn ba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun miran, ti ija si bẹrẹ.


A gbọ pe ọkunrin kan ti wọn n pe ni Tajudeen lo ṣaaju awọn Ẹiyẹ Confraternity lati Oke-Baalẹ lọ sibẹ, oun naa ni wọn si sọ pe o yinbọn lu Kazeem lori, ti iyẹn si gbabẹ ku.


A gbọ pe awọn ọlọpaa lati Anti-Cultism ni wọn lọọ gbe oku ọkunrin naa, ti wọn si ri i pe alaafia jọba lagbegbe naa.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni anfaani ọdun eegun ti wọn n ṣe lọjọ naa lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lo lati huwa laabi yii.


O ni iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣawari awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, laipẹ lọwọ pampẹ ofin yoo ba wọn.

No comments:

Post a Comment