IROYIN YAJOYAJO

Monday, 29 September 2025

Owo Kansu: Ile-ejo paṣẹ fun banki UBA lati maṣe yọnda owo fawọn APC


Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọyọ ti paṣe pe awọn alaṣẹ United Bank for Africa (UBA) ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori owo to jẹ ti awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun tijọba apapọ san sọdọ wọn laipẹ yii.


Ọjọ Aiku, Sannde to kọja ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, ẹka tipinlẹ Ọṣun ke gbajare pe ijọba apapọ ti san owo kansu to ti n fa ariyanjiyan latinu oṣu kẹta ọdun yii fun awọn alaga ati kanselọ ẹgbẹ oṣelu APC.


Alaga NULGE, Dokita Ogungbangbe sọ pe ohun ti ko ṣẹle ri, to si jep kayeefi fun awọn ni bijọba apapọ ṣe san owo oṣu mẹfa ọhun fun awọn alaga ti kootu ti le kuro lọfiisi.

 

Amọ ṣa, ninu iwe kootu kan to ni nọmba 1/1149/25, ni Amofin agba nipinlẹ Ọṣun ati ajọ to n ri si ọrọ awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun ti wọ banki UBA lọ si kootu gẹgẹ bii olujẹjọ.


Ninu iwe ipẹjọ naa, eleyii ti Olufẹmi Akande Ogundun fọwọ si lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun yii ni Agbẹjọro olupẹjọ, A. A. Abass ti rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun UBA pe wọn ko gbọdọ fọwọ kan owo naa.


Ninu idajọ rẹ lọjọ naa, Onidajọ A. L. Akintọla, ni oun fọwọ si gbogbo ibeere awọn olupẹjọ.


Lọjọ yii kannaa ni Agbẹjọro Musbau Adetunbi, SAN, kọ lẹta lọ si manija ẹka UBA to wa ni Olonkoro ni Igbọna niluu Oṣogbo lati fi abọ kootu to wọn leti.


Ninu lẹta naa ni wọn to awọn akanti tuntun ti wọn sọ pe awọn alaga APC ṣi fun ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ Ọṣun si, ti wọn si sọ pe, gẹgẹ bii banki to nigbagbọ ninu ofin, wọn gbọdọ bọwọ fun ofin ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment