Awọn alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress kaakiri wọọdu to wa nipinlẹ Ọṣun atawọn kanselọ ti ṣeleri atilẹyin wọn fun Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore lati di oludije latinu ẹgbẹ naa ninu idibo gomina ọdun to n bọ.
Awọn alaga wọọdu ọhun, ti wọn to ọọdunrun, sọ pe loootọ lawọn oludije yooku naa kunju osunwọn, ṣugbọn iriri Omiṣore ninu oṣelu ati imọ iṣakoso to ni mu un tayọ gbogbo wọn.
Nibi ipade kan to waye nile ipolongo ibo Sẹnetọ Omiṣore to wa lagbegbe Ogo-Oluwa niluu Oṣogbo ni wọn ti sọ pe irọrun ni yoo jẹ fun ẹgbẹ APC lati gbajọba l'Ọṣun ti ẹgbẹ naa ba le fa Omiṣore kalẹ.
Gbogbo wọn ni wọn ṣeleri pe awọn yoo tubọ tẹramọ mimu ipolongo ibo lọ kaakiri ẹsẹkuuku lati jẹ kawọn araalu mọ pe ẹni to kajuẹ, ti yoo si mu igbayegbadun awọn araalu lọkunkundun ni ọkunrin oloṣelu ọmọbibi ilu Ileefẹ naa.
Ninu ọrọ rẹ, aṣojuṣofin nigba kan ri, Honourable Ajibọla Famurewa ṣapejuwe Omiṣore gẹgẹ bii oloṣelu to ṣe e gbọkanle, to si ni awọn amuyẹ lati mu ẹgbẹ APC de ebute iṣẹgun.
Bakan naa ni kọmiṣanna tẹlẹ fun eto-ẹkọ, Hon. Fọlọrunṣọ Bamiṣayemi, fi da awọn alaga wọọdu atawọn kanselọ naa loju pe Omiṣore yoo ko ọrọ wọn sọkan, yoo si mu idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba ipinlẹ Ọṣun.
Sẹnetọ Omiṣore dupẹ lọwọ awọn oloṣelu naa, o ni bi wọn ṣe fontẹ lu erongba oun fi han pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ṣetan fun aṣeyọri ninu idibo gomina ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
No comments:
Post a Comment