Idibo lati yan awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni wọọdu okoolelugba o din mẹfa kaakiri ijọba ibilẹ mẹẹdọgbọn nipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ bayii loni ọjọ Satide, ogunjọ oṣu Kẹsan ọdun 2025 nidibo naa waye.
Gẹgẹ bi alaga ti awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa niluu Abuja ran wa lati ṣakoso eto idibo naa, Honourable Samuel Ọmọtọṣọ, ṣe ṣalaye, gbogbo eto lo ti to lati ri i pe idibo naa lọ nirọwọrọsẹ.
O ni ẹgbẹ to bọwọ fun ofin ni ẹgbẹ PDP, niwọn igba ti ọdun mẹrin awọn oloye to wa nibẹ tẹlẹ si ti pe, o di dandan ki awọn yan awọn oloye miran.
O ni ẹgbẹ gbagbọ ninuu ki ipilẹ to duroore wa kaakiri wọọdu, eleyii ni yoo tubọ mu ki igbadun ijọba Gomina Adeleke maa tẹ siwaju kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
Ọmọtọṣọ sọ siwaju pe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun mọriri Adeleke nitori wọn ti figba kan ri wa ni oko-ẹru, wọn ko si ṣetan lati pada sibẹ.
Ninu ọrọ tirẹ, alaga ẹgbẹ PDP l'Ọṣun, Hon. Sunday Bisi, ṣalaye pe iyatọ gedengbe to wa laarin ẹgbẹ PDP ati APC ni pe ẹgbẹ to bọwọ fun ofin ni ẹgbẹ PDP.
O ni eto idibo wọọdu naa ṣe pataki, eto aabo to peye si ti wa nilẹ fun awọn oludibo atawọn aṣoju égbẹ ti wọn wa lati Abuja.
No comments:
Post a Comment