Tako ikede alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Hon. Sunday Bisi, pe wọn ti sun idibo abẹle lati yan oludije funpo gomina siwaju, idibo ọhun ti bẹrẹ bayii.
Fọfọ ni Adolak Event Center lọna Ogo-Oluwa niluu Oṣogbo kun fun awopn dẹligeeti lati gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun.
Awọn ọlọpaa duro wamuwamu, awọn aṣoju ajọ eleto idibo wa nibẹ, bẹẹ ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa l'Abuja ran awọn aṣoju labẹ idari H. M. Humphery Abba, wa sibẹ.



No comments:
Post a Comment