IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 9 December 2025

Lẹyin ọsẹ kan to kuro ninu ẹgbẹ PDP, Gomina Adeleke darapọ mọ ẹgbẹ Accord


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ta kọsọ wọnu ẹgbẹ oṣelu Accord bayii.


Adeleke ṣe ikede yii funraarẹ lọjọ Tusidee, ọjọ kẹsan oṣu kejila ọdun 2025.


Tẹ o ba gbagbe, lọjọ keji oṣu kejila ni Adeleke kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ PDP latari wahala ti awọn adari ẹgbẹ naa n ba ara wọn fa, eleyii to ni o le ṣakoba fun idibo saa keji oun.


Ni bayii, gbogbo nnkan to pamọ tẹlẹ nipa irinajo oṣelu Gomina Adeleke lo ti han kedere. Abẹ ẹgbẹ Accord ni yoo si ti dupo fun saa keji lọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment