Gomina Ademọla Adeleke ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party silẹ bayii.
Ninu lẹta kan to kọ si alaga ẹgbẹ ni wọọdu keji, Sagba Abogunde nijọba ibilẹ Ariwa Ẹdẹ to ti maa n dibo lo ti sọ eleyii di mimọ.
O ni wahala ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ n ba ara wọn fa lorileede yii lo fa a ti oun fi kọwe fi ẹgbẹ silẹ.
O dupẹ lọwọ ẹgbẹ PDP fun anfaani ti wọn fun un lati di Sẹnetọ ati lati di gomina ipinlẹ Ọṣun.

No comments:
Post a Comment