IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 29 January 2026

Ṣe ẹ ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si Gomina Adeleke ninu ẹgbẹ oṣelu Accord?


Ẹgbẹ oṣelu Accord ti kede pe awọn ti gbe orukọ Gomina Ademọla Adeleke wọ inu akọsilẹ ajọ eleto idibo lorileede yii, INEC, gẹgẹ bii oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ Kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun yii.


Eleyii lo fopin si ahesọ ati awuyewuye kan to n lọ kaakiri pe ẹgbẹ naa le ma ni oludije ninu idibo ọhun latari bi ẹnikan ṣe tun jade pe oun ni oludije funpo gomina.


Ọgbẹni Clement Bamigbọla lawọn igun kan ninu ẹgbẹ Accord na ọwọ rẹ soke bii oludije lẹyin ti awọn adari ẹgbẹ Accord lorileede yii ti gbe asia wọn fun Adeleke, ti wọn si tun fun un ni tikẹẹti lati dupo.


Amọ ṣa, alaga ẹgbẹ naa l'Ọṣun, Pasitọ Victor Akande ti sọ pe aṣeyọri nla lo jẹ fun ẹgbẹ oun pe INEC jan orukọ Gomina Adeleke lountẹ gẹgẹ bii oludije, o ni oun si ni idaniloju pe yoo wọle ẹlẹẹkeji ninu idibo naa pẹlu ifọwọsowọpọ awọn araalu ti wọn ti ri iṣẹ rere rẹ.

No comments:

Post a Comment