Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir, lo ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party to gbe e depo gomina, to si ti darapọ mọ ẹgbẹ All Progressives Congress.
Gomina Abba ko da rin o, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mọkanlelogun nipinlẹ Kano, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ mẹjọ ati awọn alaga ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji ni wọn tẹ le e kuro ninu NNPP.
Latigba ti nnkan ti daru laarin Gomina Abba ati babaasalẹ rẹ nipinlẹ Kano, Sẹnetọ Rabiu Kwankwaso ni ahesọ ti n lọ kaakiri pe o ṣee ṣe ki ọkunrin naa kuro ninu ẹgbẹ NNPP.
Abba ṣalaye pe bi iji aye ṣe n fi ẹgbẹ NNPP lakalaka lo fa a toun fi kuro nibẹ.

No comments:
Post a Comment