IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 7 February 2026

Okete ti bo'ru mọ yin lọwọ, ko si ọgbọn ti ẹ le da lati pada sijọba l'Ọṣun - Adeleke yẹẹyẹ ẹgbẹ APC


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti sọ pe lẹyin ti gbogbo ọna di mọ gomina ana, Gboyega Oyetọla ati oludije ẹgbẹ APC, Bọla Oyebamiji, lati da wahala silẹ l'Ọṣun, ni wọn tun bẹrẹ etekete pe kijọba apapọ kede ijọba pajawiri bayii.


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita lọjọ Satide ni Adeleke ti sọ pe ẹgbẹ APC ti ri i pe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti pada lẹyin awọn, idi niyẹn ti wọn ṣe fẹẹ gba ọna eru lati gbajọba.


O ni ko sẹni ti ko mọ pe ẹgbẹ APC ni mọdaru to n da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru, wọn ko jẹ ki iṣejọba wa kaakiri ijọba ibilẹ, wọn n ṣe owo araalu baṣubaṣu, wọn si n lo agbara lati dari awọn ọlọpaa bo ṣe wu wọn, eleyii lo si mu ki awọn araalu koriira wọn. 


Adeleke sọ siwaju pe gbogbo nnkan ti ẹgbẹ APC n ṣe lati fi da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun lawọn ko wo rara, nigba ti ara si ni wọn si idakẹjẹẹ ijọba yii lo fa a ti wọn fi bẹrẹ si i pariwo pe ijọba pajawiri lo kan.


Gomina sọ siwaju pe ṣe ni esuru ẹgbẹ APC padi da, ti wọn n le aja bayii, Oyetọla atawọn abẹṣinkawọ rẹ ni wọn mu akude ba iṣakoso nijọba ibilẹ, awọn naa ni wọn tun n pariwo kaakiri bayii pe ipinlẹ Ọṣun ko fararọ.


O ni gbogbo awọn araalu ni wọn ti ri i pe ẹgbẹ to jẹ ọta wọn ati ẹgbẹ to mu inira lọwọ ni ẹgbẹ APC, idi niyii ti wọn fi duro wamuwamu pẹlu iṣejọba to wa lode, ti wọn si ṣetan lati fi ibo wọn gbe e wọle lẹẹkeji loṣu kẹjọ ọdun yii.


Gomina Adeleke wa kilọ fun awọn adaluru lati wa iṣẹ ṣe nitori ipinlẹ Ọṣun ko nii faaye gba ẹgbẹ kankan lati da wahala silẹ, ẹni to ba si ṣe bẹẹ yoo fimu kata ofin.


O ni gbogbo erongba ẹgbẹ APC ni lati da rogbodiyan silẹ nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn okete ti boru mọ wọn lọwọ bayii, ko si aaye fun wọn lati pada sori aleefa.


Adeleke ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati kilọ fun Oyetọla nitori iwa to n ta'po saṣọ aala aarẹ lo n hu l'Ọṣun.

No comments:

Post a Comment