IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 February 2026

Inira yii pọ, ẹ ba wa yanju wahala owo ijọba ibilẹ l'Ọṣun - Awọn oṣiṣẹfẹyinti rawọ ẹbẹ si Tinubu


Ogunlọgọ awọn oṣiṣẹfẹyinti onimọda-mọda, Contributory Pension Scheme, nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bọla Tinubu lati da si wahala ai san owo awọn ijọba ibilẹ lati oṣu mejila sẹyin.


Wọn ni bijọba apapọ ṣe gbẹsẹ le owo naa ti ko inira ti ko lẹgbẹ ba awọn oṣiṣẹfẹyinti nitori ninu owo yii ni wọn ti maa n gba owo ajẹmọnu oloṣooṣu wọn.



Nibi ipade oniroyin kan ti wọn ṣe niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni wọn ti ke gbajare pe ki Tinubu ba awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, APC, nipinlẹ Ọṣun sọrọ lati faaye gba ifikunlukun lori ọrọ owo to wa lakata ijọba apapọ yii.


Oniruuru akọle ni wọn gbe lọwọ nibi eto naa, lara rẹ ni wọn ti kọ pe 'Ai san owo awọn kansu fun ipinlẹ Ọṣun ti mu inira ba wa', 'Ko too bọ sori, Aarẹ Tinubu, ba wa da si ọrọ yii', ati bẹẹ bẹẹ lọ.


Ninu atẹjade ti Alhaji Ayinde Toyeen, Alakoso wọn l'Ọṣun, Pasitọ Adepọju Sunday to jẹ alaga wọn ati Alhaja Abidoye, to jẹ alaga keji, jumọ ka ni wọn ti gboṣuba fun oniruuru awọn igbesẹ ti Gomina Ademọla Adeleke ti gbe lati mu ki aye tu wọn lara.


Lara awọn igbesẹ naa ni sisan oṣu mejidinlọgbọn ninu idaji owo-oṣu tijọba atẹyinwa jẹ wọn, sisan ẹgbẹrun mẹwaa naira gẹgẹ bii owo palietiifu loṣooṣu, fifi orukọ awọn oṣiṣẹfẹyinti silẹ ninu eto ilera adojutofo ọfẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.


Wọn sọ siwaju pe, pẹlu gbogbo eleyii, ọpọ awọn oṣiṣẹfẹyinti nileewe alakọbẹrẹ, ijọba ibilẹ, ileewe girama, ile-ẹkọ giga atawọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn ko tii gba ajẹmọnu to tọ si wọn.


Awọn oṣiṣẹfẹyinti onimọda-mọda yii fi kun ọrọ wọn pe ijọba Tinubu ni lati tete da si ọrọ yii ki iku aitọjọ ma baa ṣẹlẹ laarin awọn oṣiṣẹfẹyinti latari ai ri owo tọju ara wọn.


"A jẹ ẹni to bọwọ fun ofin, bẹẹ ni a si jẹ olootọ si orileede Naijiria. A n bẹbẹ pe kijọba apapọ tete da si ọrọ yii fun anfaani ọmọniyan, idajọ ododo ati ohun to bojumu."

No comments:

Post a Comment