Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti ke si gbogbo awọn to du tikẹẹti gomina ninu ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ papọ pẹlu oludije wọn, Aṣiwaju Munirudeen Bọla Oyebamiji, fun aṣeyọri idibo ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Nibi ipade kan to waye nile alaga wọn, Ẹnjinia Sọla Akinwumi, niluu Ilobu lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni wọn ti gbalejo Oyebamiji, ti wọn si sọ pe lati yuniiti ni aṣeyọri idibo ti maa n bẹrẹ, nitori naa, gbogbo ọmọ ẹgbẹ gbọdọ mura daadaa.
Wọn gboṣuba fun awọn lookọlookọ ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti bẹrẹ lati le ri i pe ẹgbẹ ọhun jawe olubori, bẹrẹ latinu idibo gomina oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Igbimọ yii ṣẹleri pe ko nii si yiyan ẹnikẹni nipọsin ninu ẹgbẹ naa, agbajọwọ ni wọn yoo fi gbogbo nnkan ṣe.
Ẹnjinia Akinwumi wa ki gbogbo awọn Musulumi ku ayọ oju wọn to ri ibẹrẹ oṣu Ramadan, o si gbadura pe ki Allah bu kun wọn.


No comments:
Post a Comment