Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Hon. Adewale Ẹgbẹdun, ti sọ pe gbedeke wa fun anfaani ominira ti ile-ẹjọ to ga julọ lorileede yii fun awọn ijọba ibilẹ lori eto iṣuna.
O ni ominira yii ko lagbara lori ohun to wa ni abala Keje iwe ofin orileede yii eyi to fun ileegbimọ aṣofin ipinlẹ ni agbara lati ṣofin ti yoo ṣalakalẹ bi wọn ṣe gbọdọ na iru owo bẹẹ ati bi akoyawọ ṣe gbọdọ wa.
Nigba to n sọrọ lorii bi wọn ṣe ni ijọba apapọ san owo awọn ijọba ibilẹ to n da awuyewuye silẹ bayii si ileefowopamọ UBA, ti awọn oṣiṣẹ ibẹ si ti n fun awọn alaga ẹgbẹ APC ni owo naa bayii.
O ni ẹnikẹni ko gbọdọ lero pe awọn alaga kansu ni agbara lati na owo to wa latọdọ ijọba apapọ bo ṣe wu wọn lai gba aṣẹ latọdọ awọn aṣofin nibamu pẹlu ofin.
Ẹgbẹdun kilọ fun banki UBA lati dẹkun iwa to lodi si ofin ti wọn n hu, o ni agbara wọn ko nii ka a nigba ti atubọtan rẹ ba de.
Bakan naa lo kilọ fun gomina ana l'Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ẹni to ni o wa nidi owo ti awọn alaga ẹgbẹ APC n gba latọdọ ijọba apapọ yii.
O ni Oyetọla ko ni agbara kankan labẹ ofin lati maa da si ọrọ inawo ni kansu, paapaa, lẹyin ti ile ẹjọ ti le awọn alaga ẹgbẹ APC yii kuro lọfiisi, ti saa wọn ti wọn n pariwo gan an si ti kẹnu-bọ'do lati oṣu Kẹwa ọdun 2025.
O ni ko sẹnikankan to ga ju ofin lọ, bẹẹ ni ile igbimọ aṣofin ko nii gba ki Oyetọla dabaru alaafia to ti n jọba nipinlẹ Ọṣun pẹlu iwa taa-ni-yoo-mu-mi to n hu.

No comments:
Post a Comment