Traditional Religion Worshipers Association (TRWASO) ẹka tipinlẹ Ọṣun ti ke si ajọ INEC lati sun ọjọ idibo gomina ipinlẹ Ọṣun siwaju.
Ninu lẹta kan ti alaga ẹgbẹ naa, Dokita Oluṣeyi Atanda kọ si ajọ INEC ni wọn ti sọ pe ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ ọdun yii ti wọn mu ọhun ti bọ sinu ọsẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo.
O ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keje si ọjọ Keje oṣu Kẹjọ ni ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo, o si maa n to aago mẹfa alẹ ki ayẹyẹ ọdun naa to pari lọjọ ti idibo yoo ku ọla yii.
Trwaso sọ siwaju pe ko ṣe e ṣe lati sun ayẹyẹ ọdun Oṣogbo nitori igva meji ti wọn ti ṣe bẹẹ ri, atubọtan rẹ lagbara.
Ẹgbẹ naa sọ siwaju pe awọn janduku le lo anfaani ero to maa n wa sibi ayẹyẹ naa lati da wahala silẹ saaju idibo gomina, eyi to si lewu pupọ.
O rọ ajọ INEC lati gba ọrọ naa ro, ki wọn si sun idibo naa siwaju.



No comments:
Post a Comment