IROYIN YAJOYAJO

Friday, 6 February 2026

Ẹni to ba wọ aafin Akirun lodi si aṣẹ mi yoo kabamọ - Gomina Adeleke


Gomina Ademọla Adeleke ti kilọ fun gbogbo awọn ti wọn n gbero lati wọnu aafin Akirun nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun lati tun ero wọn pa nitori ijọba rẹ ko nii faaye gba ẹnikẹni lati da omi alaafia agbegbe naa ru.


Adeleke ti wa paṣẹ fun awọn agbofinro lati maṣe turasilẹ, ki wọn ri i pe aabo to peye wa layika aafin naa.


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita lo ti sọ pe ọmọọba ti ajere iwa idaluru naa ba ṣi mọ lori yoo kabamọ rẹ.


Adeleke ṣalaye pe ọrọ nipa ipo Akirun wa nile-ẹjọ, aafin naa yoo si wa ni titipa titi di igba ti ẹjọ naa yoo fi pari, nitori naa, ẹnikankan ko gbọdọ lero pe oun le huwa to wu oun nibẹ.


O ni "Aṣẹ mi ni mo fi da alaafia pada siluu Ikirun, emi naa si ni mo le paṣẹ pe ki wọn ṣi aafin yẹn. A kan ṣi i laipẹ yii lati le jẹ ki wọn ṣanko ibẹ, ki aabo le wa fun ọkan lara awọn ibudo nnkan isẹmbaye wa. Nitori naa, mo n paṣẹ bayii fun awọn agbofinro lati maṣe faaye gba ẹnikẹni lati wọnu aafin naa lọna aitọ, ojuṣẹ gbogbo wa ni lati ri i pe alaafia to n jọba niluu Ikirun bayii tẹ siwaju."


Tẹ o ba gbagbe, nigba to ku diẹ kijọba gomina ana l'Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, kogba wọle lo yan awọn ọba kan, lara wọn si ni Akirun, Ọba Yinusa Ọlalekan Akadiri, ṣugbọn bi Gomina Adeleke ṣe gbajọba lo paṣẹ pe ki awọn ọba naa yẹba lori oye titi digba ti igbimọ toun gbe kalẹ lori ọrọ wọn yoo pari iṣẹ.


Bakan naa ni awọn ọlọmọọba ilu naa gbe oniruuru ẹjọ dide lori iyansipo rẹ, ti wọn si wa ni kootu bayii.

No comments:

Post a Comment