IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 March 2026

Adejare Bello di alaga igbimọ alakoso Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ileefẹ


Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu la gbọ pe o ti yan aṣoju orileede yii ni United Mexican States tẹlẹ, Anbasadọ Rafiu Adejare Bello, gẹgẹ bii alaga igbimọ alakoso Obafemi Awolowo University, Ileefẹ.

Bello, ọmọbibi ilu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun, lo jẹ olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress si ni.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọgbọn Ṣiyan Oyewẹsọ to jẹ alaga igbimọ naa tẹlẹ lo doloogbe loṣu Kejila ọdun to kọja. Ọmọbibi ilu Ẹdẹ loun naa.

No comments:

Post a Comment