IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 March 2026

Sunday Bisi ko lagbara lati sọrọ lorukọ ẹgbẹ PDP, ṣe lo n tan Adeleke - Bamidele


Akọwe igun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ọṣun, Ṣeyi Bamidele, ti sọ pe ofuutufẹẹtẹ, ofo ọjọkeji ọja ni aṣẹ ti alaga igun keji ẹgbẹ naa l'Ọṣun, Sunday Bisi, pa pe ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ dibo fun Gomina Ademọla Adeleke ninu idibo gomina to n bọ.


Bamidele sọ pe igbimọ apapọ ẹgbẹ PDP lorileede yii ti tu igbimọ ti Bisi n ṣe alaga le lori ka, nitori naa ko lagbara tabi aṣẹ lati sọrọ nipa ẹgbẹ naa mọ, ṣe lo kan n tan Adeleke jẹ.


Nibi ipade awọn lookọlookọ ẹgbẹ PDP to waye niluu Osogbo lọjọ Mọnde ni Sunday Bisi ti sọ pe Adeleke, ẹni to jẹ oludije latinu ẹgbẹ Accord ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP dibo wọn fun ki iṣẹ rere to n ṣe l'Ọṣun le tẹ siwaju.


Ṣugbọn Bamidele sọ pe igbimọ adele ti wa nipinlẹ Ọṣun labẹ idari alaga wọn, Tunde Tijani, gbogbo igbesẹ ti yoo si mu ki oludije ẹgbẹ naa rọwọ mu ninu idibo ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ, ọdun yii lawọn n gbe bayii.


O ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP maṣe ka ọrọ Bisi si rara nitori awọn adari apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii nikan ni wọn le sọrọ lori nnkan to ba jẹ mọ ṣiṣe iṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu miran, ko si ẹni to ni iru agbara bẹẹ.


Bamidele sọ siwaju pe digbi ni ẹgbẹ PDP wa kaakiri gbogbo wọọdu atijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ si jẹ olotitọ ti wọn ko nii faaye gba ẹnikẹni lati ṣi wọn lọna.

No comments:

Post a Comment