IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 March 2026

Awọn eeyan Ọdọ-Ọtin fariga, wọn ni awọn lo kan lati fa aṣojuṣofin kalẹ lọdun 2027


Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe tijọba, Odo-Ọtin Lo Kan Parrot Movement, ti ke si gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu to wa lagbegbe Ifẹlodun/Boripẹ/Odo-Ọtin (IBO) lati faaye gba ijọba ibilẹ wọn lati fa aṣofin ti yoo ṣoju wọn l'Abuja kalẹ.


Ninu atẹjade kan ti alakoso wọn, Bright Oyewumi, fi sita lawọn ọdọ ilu Odo-Ọtin ti sọ pe latigba tijọba tiwantiwa ti bẹrẹ lọdun 1999, awọn eeyan Ifẹlodun ati Boripẹ lo maa n fa aṣojuṣofin kalẹ, ẹẹkan ṣoṣo lanfaani naa lọ si Odo-Ọtin ri.


Wọn ni awọn eeyan agbegbe mẹtẹẹta yii gbọdọ faaye gba oṣelu akoyawọ, ti ko fi sibi kan ju ibikeji lọ, nitori naa, ki wọn faaye gba Odo-Ọtin lati fa ẹni ti yoo ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin apapọ lọdun to n bọ kalẹ.


Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, laarin ọdun 1999 si 2003, Hon. Abioye Oyetunji lati Ifẹlodun lo wa nibẹ, laarin ọdun 2003 si 2005, Hon. Lanti Alabi lati Odo-Ọtin lo ọgbọn oṣu pere, Hon. Kayọde Idowu to wa lati Boripẹ lo wa nibẹ laarin ọdun 2005 si 2011, nigba ti Hon. Adeyanju Adeyinka lati Boripẹ wa nibẹ laarin ọdun 2011 si 2019.


Nigba to di ọdun 2019, wọn yan Hon. Rasheed Afọlabi lati Ifẹlodun, o si kuro lọdun 2023, wọn si yan Hon. Olusọji Abidemi to wa nibẹ bayii lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun ni ọdun 2023, idi si niyẹn ti wọn fi n sọ pe irẹjẹ lo maa n fọ ẹgbẹ, ohun to tọ ni ki wọn faaye gba ijọba ibilẹ Odo-Ọtin lati fa ẹni ti yoo ṣoju IBO kalẹ.


Wọn ke si gbogbo awọn lookọlookọ ninu oṣelu latijọba ibilẹ mẹtẹẹta lati gba ọrọ yii yẹ wo, ki wọn si ṣe ohun to tọ.

No comments:

Post a Comment