Titi di asiko ti a n koroyin yii jọ, wọn ko tii bẹrẹ idibo igbimọ awọn alaga ẹgbẹ oṣelu, IPAC, to yẹ ko waye nipinlẹ Ọṣun.
Idibo naa ni wọn fi si aago mẹwaa aarọ ọjọ Satide, ọjọ Kẹrinla, oṣu kẹta ọdun yii, to si yẹ ko waye ninu ọgba ajọ eleto idibo, INEC.
Gbogbo awọn to yẹ ki wọn ṣeto idibo naa lati ọfiisi apapọ IPAC l'Abuja la gbọ pe wọn ti de siluu Oṣogbo lati ọjọ Furaidee ọsẹ yii, ṣugbọn wọn ko yọju sibi idibo.
Ni aago meji kọja iṣeju mẹẹdogun ọsan ọjọ Satide, wọn ko bẹrẹ, koda, gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogun ti wọn yoo kopa ninu idibo naa ti wọn ti kọkọ de sibẹ ni wọn tun ti kuro bayii.
Akọwe eto fun IPAC lorileede yii, Chiyere Kalu, sọ pe eto naa yoo bẹrẹ laipẹ, bẹẹ ni alaga IPAC to jẹ alaga ACCORD l'Ọṣun, Victor Akande, sọ pe awọn yoo bẹrẹ eto laipẹ.

No comments:
Post a Comment