Ọmọọba Lawal Ọbẹlawọ, to jẹ gbajugbaja onisowo niluu Oṣogbo, ni wọn ti sọ pe o jade laye bayii.
Inu oṣu karun ọdun yii ni baba naa i ba pe ọmọ ọdun mérindinlọgọrun loke eepẹ.
Oun ni oludasilẹ Lopin Nigeria Limited, o si ni ẹka ni orileede France, Ivory Coast ati UK.
Ilu Ejigbo nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti bi Ọmọọba yii, o si bẹrẹ okoowo rẹ ni Abidjan ko too di pe o gbẹrẹgẹdigẹ niluu Oṣogbo.

No comments:
Post a Comment