Alaga Igbimọ Agba Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti ranṣẹ ikini ku oriire si Ọjọgbọn Isaac Adewọle ati Ọnarebu Adejare Bello lori iyansipo wọn to waye laipẹ yii.
Adewọle ni Aarẹ Bọla Tinubu yan gẹgẹ bii aṣoju orileede Naijiria si orileede Canada, nigba ti wọn yan Adejare gẹgẹ bii alaga igbimọ oluṣakoso Ọbafemi Awolowo University niluu Ileefẹ.
Ninu atẹjade ti Akinwumi fọwọ si lorukọ igbimọ naa lo ti dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, Oloye Bisi Akande ati Alhaji Adegboyega Oyetọla fun ipa ti wọn ko lori awọn iyansipo ọhun.
O ni oun nigbagbọ kikun ninu awọn mejeeji pe wọn yoo lo omi ọgbọn wọn lati fi mu ki orileede Naijiria tubọ dagbasoke nipasẹ ojuṣe tuntun ti wọn gba yii.
Akinwumi gbadura pe ki Ọlọrun mu wọn ṣaṣeyọri si rere, ko si dari wọn lati maṣe ya ara wọn kuro lọdọ awọn araalu.
O wa ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC Ọṣun lati maṣe kaarẹ ninu oniruuru awọn igbesẹ ti yoo mu ki ẹgbẹ naa jawe olubori ninu idibo gomina ọjọ Keeẹdogun oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

No comments:
Post a Comment