Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori ifikunlukun awọn araalu, Abdullahi Yakassai, ti sọ pe inu aibalẹ aya ni aarẹ wa latari bi eto aabo ilẹ yii ko ṣe duroore.
Nibi ifọrọwerọ ori tẹlifisan kan ni Yakassai ti sọ laipẹ yii pe bo tilẹ jẹ pe wahala naa ti n din ku diẹdiẹ, sibẹ, awọn agbebọn yii tun ti n wọle lọna tuntun miran bii iru eyi to n ṣẹlẹ nipinlẹ Kwara bayii.
O ni Aarẹ Tinubu ko le sun, ọsọọsẹ lo ku to n ṣepade pẹlu awọn ẹṣọ alaabo nile ijọba lori wahala naa.
O sọ siwaju pe kaka kewe agbọn ọrọ naa dẹ, lile lo n le koko sii, nitori bi ileeṣẹ ologun ba ti gbe igbesẹ kan lonii lawọn agbebọn naa yoo tun gba ọna miran yọl lọla.
Yakassai sọ pe ki i ṣe asiko lati di ẹbi gbogbo rẹ ru ijọba niyii nitori awọn to wa nidi rẹ fẹẹ lo o lati ba orukọ ijọba to wa lode jẹ ni, ṣe lo si yẹ ki gbogbo araalu fọwọsowọpọ lati ṣẹgun wahala naa.
O ni awọn agbebọn yii ti sa kuro ni Abuja, Kaduna ati Zamfara, wọn si ti lọ si agbegbe Niger ati Kwara, idi si niyẹn to fi jẹ pe ipinlẹ Kwara ni ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii lọ ni kete ti wọn yan an.
Yakassai sọ siwaju pe ki awọn araalu fọkanbalẹ nitori oun nidaniloju pe, pẹlu akoko, ogun naa yoo ṣẹ patapata.

E ku ise. Ede Yoruba ko nii parun lase Eledua 🙏
ReplyDelete