IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 24 March 2026

L'Ọṣun, awọn tọọgi lu awọn Amọtẹkun lalubami, wọn tun gbe ibọn wọn lọ


Titi digba ti a n koroyin yii jọ, ọfiisi ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ko tii ri ibọn ti awọn janduku ti wọn ya bo wọn niluu Awo nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ nipinlẹ Ọṣun lalẹ ọjọ Mọnde, ọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹta, ọdun yii gba pada.


Idije bọọlu la gbọ pe o fa ariyanjiyan laaarin awọn ọkunrin meji niluu Awo lalẹ ọjọ Sannde, bo ṣe di alẹ Mọnde ni ọkan lara wọn dena de ekeji pẹlu awọn tọọgi nigba ti iyẹn n bọ latile olounjẹ.


Gẹgẹ bi alukoro ajọ Amọtẹkun Ọṣun, Yusuf Idowu Abass, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita, wọn dawọ jọ lu ọkunrin naa pẹlu igi, ada atawọn nnkan ija miran, iyẹn si jajabọ, o sare wọnuu ọfiisi awọn Amọtẹkun fun aabo ẹmi rẹ.


Ṣugbọn ṣe ni awọn tọọgi naa lọ tunra mu, wọn ya bo awọn Amọtẹkun ti wọn ba lọfiisi, wọn lu wọn lalubami, wọn ba nnkan jẹ, bẹẹ ni wọn tun ji ibọn wọn gbe lọ.


Abass sọ siwaju pe lẹyin wahala naa, ọwọ Amọtẹkun pada ba marun lara awọn tọọgi ọhun, wọn si ti fa wọn le DPO ọlọpaa ilu Awo lọwọ fun seria to yẹ.


O ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣawari awọn ibọn ti awọn janduku ọhun gbe lọ, bẹẹ ni wọn rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro nipa titawọn-lolobo loorekoore lori iṣẹ iwadii naa.

No comments:

Post a Comment