Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Oluwoo ti ilu Iwo nipinlẹ Ọṣun, ti gboṣuba fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun oniruuru awọn iṣẹ idagbasoke to n ṣe kaakiri orileede Naijiria latigba to ti de ori aleefa.
Ọba Akanbi ṣalaye pe ṣe ni Eledua fi Tinubu jinki orileede Naijiria, paapaa, iran Yoruba nitori ko tii si aarẹ to mu nnkan yatọ ni gbogbo ẹka iṣejọba bii ti Tinubu.
Nigba ti awọn ikọ City Boy Movement ṣabẹwo saafin rẹ niluu Iwo laipẹ yii ni Ọba Akanbi sọ pe manigbagbe ni eto iranwọ fun awọn akẹkọọ, iyẹn NELFUND, ti iṣejọba yii gbe kalẹ jẹ nitori o n fun awọn akẹkọọ lanfaani lati kawe pẹlu irọrun.
O ni ilọpo mẹrin owo lo n wọle sapo awọn gomina loṣooṣu bayii eleyii to n mu ki ọwọja iṣẹ idagbasoke wa kaakiri.
Ni ti ominira awọn ijọba ibilẹ, Oluwoo sọ pe bi aarẹ ṣe faaye gba a ran awọn eeyan ẹsẹkuku lọwọ pupọ, o si mu ki awọn alaga kansu ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ.
Ọba Akanbi wa sọ pe pẹlu gbogbo nnkan wọnyii, Tinubu ṣe daadaa, o si tọ si saa keji rẹ ninu idibo apapọ ọdun to n bọ. O si ṣeleri lati ṣiṣẹ tọ eleyii.
Ṣaaju ninu ọrọ alakoso agba fun City Boy Movement l'Ọṣun, Ẹnjinia Kayọde Ṣowade, o ni ohun ti awọn n ṣe ni lati fọnrere iṣẹ ribiribiri ti Aarẹ Tinubu n ṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
O ke si gbogbo awọn eeyan ilu Iwo ati agbegbe rẹ lati gbaruku ti iṣejọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ki wọn si faaye gba a fun saa keji, o si rọ wọn lati dibo fun ẹgbẹ APC ninu idibo gomina to n bọ lọna nipinlẹ Ọṣun.

No comments:
Post a Comment