Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe awọn ko tii gbe igbesẹ kankan lori ọrọ Apetumodu ti ilu Ipetu, Ọba Joseph Oloyede, to n ṣẹwọn lọwọ lorileede Amẹrika.
Laipẹ ni iroyin kan jade pe ijọba ti paṣẹ pe ki wọn rọ Ọba Oloyede loye, ti wọn si kede pe ko si Apetu kankan lori itẹ mọ.
Ṣugbọn atẹjade kan latọwọ akọwe agba fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọṣun, Olufẹmi Ogundun, ke si awọn araalu Ipetumodu lati kọti ọgbọnin si ahesọ naa.
Ogundun ṣalaye pe ahesọ naa ko jade latọdọ ijọba. O ni ijọba ti ṣepade pẹlu awọn ti ọrọ kan niluu Ipetumodu, awọn si ti n gbe igbesẹ lọwọ nilana ofin lori ọrọ naa.
O ni nigba to ba to asiko, gbogbo araalu yoo mọ ohun tijọba ti n ṣe lori ọrọ Apetumodu.

No comments:
Post a Comment